Native Bible

Exodus 29:34 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ohun kan nínú ẹran àgbò ìyàsímímọ́ tàbí nínú àkàrà náà bá kù di òwúrọ̀, nígbà náà ni kí ìwọ fi iná sun wọn. A kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́, nítorí mímọ́ ni.

Exodus 29:34 in English

Exodus 29:34 · Berean Standard Bible

And if any of the meat of ordination or any bread is left until the morning, you are to burn up the remainder. It must not be eaten, because it is sacred.

Context

32Ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ ni Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò ti jẹ ẹran àgbò náà àti àkàrà náà tí ó wà nínú apẹ̀rẹ̀. 33Wọn yóò sì jẹ nǹkan wọ̀nyí èyí tí a fi ṣe ètùtù náà fún ìyàsímímọ́ àti ìsọdimímọ́ wọn. Ṣùgbọ́n àlejò ni kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí pé mímọ́ ni. 34Bí ohun kan nínú ẹran àgbò ìyàsímímọ́ tàbí nínú àkàrà náà bá kù di òwúrọ̀, nígbà náà ni kí ìwọ fi iná sun wọn. A kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́, nítorí mímọ́ ni. 35“Báyìí ni ìwọ yóò ṣì ṣe fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ bí ohun gbogbo ti mo paláṣẹ fún ọ, ọjọ́ méje ni ìwọ yóò fi yà wọ́n sí mímọ́. 36Ìwọ yóò sì máa pa akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ní ojoojúmọ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù. Ìwọ yóò sì wẹ pẹpẹ mọ́ nípa ṣíṣe ètùtù fún un, ìwọ yóò sì ta òróró sí i láti sọ ọ́ dí mímọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.