Eksodu 27:13
Exodus 27:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ìhà ìlà-oòrùn, sí ibi tí oòrùn tí ń jáde, àgbàlá náà yóò jẹ́ mita mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀.
Exodus 27:13 in English
Exodus 27:13 · Berean Standard Bible
The east side of the courtyard, toward the sunrise, is to be fifty cubits wide.
Context
11Kí ìhà àríwá náà jẹ́ mita mẹ́rìndínláàádọ́ta ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa, pẹ̀lú ogun òpó àti ogún ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà tí ó sì di àwọn òpó mú. 12“Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, àgbàlá náà yóò jẹ́ mita mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, kí ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá. 13Ní ìhà ìlà-oòrùn, sí ibi tí oòrùn tí ń jáde, àgbàlá náà yóò jẹ́ mita mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀. 14Aṣọ títa ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní gíga ní yóò wà ní ìhà ẹnu-ọ̀nà, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta, 15àti aṣọ títa ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní gíga yóò wá ní ìhà kejì, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.