Native Bible

Exodus 27:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí ìhà àríwá náà jẹ́ mita mẹ́rìndínláàádọ́ta ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa, pẹ̀lú ogun òpó àti ogún ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà tí ó sì di àwọn òpó mú.

Exodus 27:11 in English

Exodus 27:11 · Berean Standard Bible

Likewise there are to be curtains on the north side, a hundred cubits long, with twenty posts and twenty bronze bases, and with silver hooks and bands on the posts.

Context

9“Ìwọ yóò sì ṣe àgbàlá fún àgọ́ náà. Ní ìhà gúúsù, ó gbọdọ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ (mita mẹ́rìndínláàádọ́ta) ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́, 10pẹ̀lú ogún òpó àti ogún ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà, kí ó sì di àwọn òpó mú. 11Kí ìhà àríwá náà jẹ́ mita mẹ́rìndínláàádọ́ta ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa, pẹ̀lú ogun òpó àti ogún ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà tí ó sì di àwọn òpó mú. 12“Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, àgbàlá náà yóò jẹ́ mita mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, kí ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá. 13Ní ìhà ìlà-oòrùn, sí ibi tí oòrùn tí ń jáde, àgbàlá náà yóò jẹ́ mita mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.