Eksodu 27:9
Exodus 27:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ìwọ yóò sì ṣe àgbàlá fún àgọ́ náà. Ní ìhà gúúsù, ó gbọdọ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ (mita mẹ́rìndínláàádọ́ta) ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́,
Exodus 27:9 in English
Exodus 27:9 · Berean Standard Bible
You are also to make a courtyard for the tabernacle. On the south side of the courtyard make curtains of finely spun linen, a hundred cubits long * on one side,
Context
7A ó sì bọ àwọn òpó náà ní òrùka, wọn yóò sì wà ní ìhà méjèèjì pẹpẹ nígbà tí a bá rù ú. 8Ìwọ yóò sì ṣe pákó náà ni oníhò nínú. Ìwọ yóò sí ṣe wọ́n bí èyí tí a fihàn ọ́ ní orí òkè. 9“Ìwọ yóò sì ṣe àgbàlá fún àgọ́ náà. Ní ìhà gúúsù, ó gbọdọ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ (mita mẹ́rìndínláàádọ́ta) ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́, 10pẹ̀lú ogún òpó àti ogún ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà, kí ó sì di àwọn òpó mú. 11Kí ìhà àríwá náà jẹ́ mita mẹ́rìndínláàádọ́ta ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa, pẹ̀lú ogun òpó àti ogún ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà tí ó sì di àwọn òpó mú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.