Eksodu 25:9
Exodus 25:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí ti mo fihàn ọ́, nípa àpẹẹrẹ àgọ́, àti àpẹẹrẹ gbogbo ohun èlò inú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó sì ṣe é.
Exodus 25:9 in English
Exodus 25:9 · Berean Standard Bible
You must make the tabernacle and design all its furnishings according to the pattern I show you.
Context
7àti òkúta óníkìsì àti òkúta olówó iyebíye ti a fi ṣe ọ̀ṣọ́ sí ara ẹ̀wù efodu àti ẹ̀wù ìgbàyà. 8“Nígbà náà ni ìwọ yóò jẹ́ kí wọn kọ́ ibi mímọ́ fún mi. Èmi yóò sì máa gbé ní àárín wọn. 9Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí ti mo fihàn ọ́, nípa àpẹẹrẹ àgọ́, àti àpẹẹrẹ gbogbo ohun èlò inú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó sì ṣe é. 10“Wọn yóò sì fi igi ṣittimu ṣe àpótí, ìgbọ̀nwọ́ méjì ààbọ̀ ni gígùn rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀ rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni gíga rẹ̀. 11Ìwọ ó sì fi ojúlówó wúrà, bò ó ní inú àti ní òde, ìwọ ó sì fi wúrà gbá etí rẹ̀ yíká.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.