Eksodu 25:26
Exodus 25:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ ó sì da òrùka wúrà mẹ́rin fún tábìlì náà, ìwọ ó sì fi òrùka kọ̀ọ̀kan sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin.
Exodus 25:26 in English
Exodus 25:26 · Berean Standard Bible
Make four gold rings for the table and fasten them to the four corners at its four legs.
Context
24Ìwọ ó sì fi ojúlówó wúrà bò ó, ìwọ ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí i ká. 25Ìwọ sì ṣe etí kan ní ìbú àtẹ́lẹwọ́ sí i yíká, ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí etí rẹ̀ ká. 26Ìwọ ó sì da òrùka wúrà mẹ́rin fún tábìlì náà, ìwọ ó sì fi òrùka kọ̀ọ̀kan sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. 27Ní abẹ́ ìgbátí náà ni àwọn òrùka náà yóò wà fún ibi ọ̀pá láti máa fi gbé tábìlì náà. 28Ìwọ ó sì fi igi kasia ṣe àwọn ọ̀pá, ìwọ ó sì fi wúrà bò wọ́n, láti máa fi wọ́n gbé tábìlì náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.