Eksodu 25:24
Exodus 25:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ ó sì fi ojúlówó wúrà bò ó, ìwọ ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí i ká.
Exodus 25:24 in English
Exodus 25:24 · Berean Standard Bible
Overlay it with pure gold and make a gold molding around it.
Context
22Níbẹ̀, ni òkè ìtẹ́, ní àárín kérúbù méjèèjì ti ó wà ni orí àpótí ẹ̀rí ni èmi yóò ti pàdé rẹ, ti èmi yóò sì fún ọ ní àwọn òfin mi fún àwọn ọmọ Israẹli. 23“Fi igi kasia kan tábìlì: ìgbọ̀nwọ́ méjì ní gígùn ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ní gíga. 24Ìwọ ó sì fi ojúlówó wúrà bò ó, ìwọ ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí i ká. 25Ìwọ sì ṣe etí kan ní ìbú àtẹ́lẹwọ́ sí i yíká, ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí etí rẹ̀ ká. 26Ìwọ ó sì da òrùka wúrà mẹ́rin fún tábìlì náà, ìwọ ó sì fi òrùka kọ̀ọ̀kan sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.