Native Bible

Exodus 25:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ ó sì da òrùka wúrà mẹ́rin fún. Ìwọ ó sì fi wọ́n sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ẹsẹ̀ rẹ̀, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹgbẹ́ kejì.

Exodus 25:12 in English

Exodus 25:12 · Berean Standard Bible

Cast four gold rings for it and fasten them to its four feet, two rings on one side and two on the other.

Context

10“Wọn yóò sì fi igi ṣittimu ṣe àpótí, ìgbọ̀nwọ́ méjì ààbọ̀ ni gígùn rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀ rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni gíga rẹ̀. 11Ìwọ ó sì fi ojúlówó wúrà, bò ó ní inú àti ní òde, ìwọ ó sì fi wúrà gbá etí rẹ̀ yíká. 12Ìwọ ó sì da òrùka wúrà mẹ́rin fún. Ìwọ ó sì fi wọ́n sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ẹsẹ̀ rẹ̀, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹgbẹ́ kejì. 13Ìwọ ó sì fi igi kasia ṣe ọ̀pá mẹ́rin, ìwọ ó sì fi wúrà bò wọ́n. 14Ìwọ ó sì fi ọ̀pá náà bọ òrùka ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan àpótí ẹ̀rí náà láti fi gbé e.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.