Eksodu 22:12
Exodus 22:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ti wọ́n bá jí ẹranko náà gbé ni ọ̀dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, yóò san ẹ̀san padà fún olúwa rẹ̀.
Exodus 22:12 in English
Exodus 22:12 · Berean Standard Bible
But if the animal was actually stolen from the neighbor, he must make restitution to the owner.
Context
10“Bí ẹnikẹ́ni bá fún aládùúgbò rẹ̀ ní kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, akọ màlúù, àgùntàn tàbí ẹranko mìíràn láti bá òun tọ́jú rẹ̀, tí ó sì kú, tàbí tí ó fi ara pa, tàbí tí a jí gbé, níbi tí kò ti sí ẹni tí o ṣe àkíyèsí. 11Wọn yóò búra sí ọ̀rọ̀ náà láàrín ara wọn ni iwájú Olúwa láti fihàn pé òun kò ní ọwọ́ nínú sísọnù ohun ọ̀sìn náà, olóhun gbọdọ̀ gba bẹ́ẹ̀, a kò sì ní san ohunkóhun fún un. 12Ṣùgbọ́n ti wọ́n bá jí ẹranko náà gbé ni ọ̀dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, yóò san ẹ̀san padà fún olúwa rẹ̀. 13Bí ẹranko búburú bá fà á ya, ó ní láti mú àyakù ẹran náà wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí, kò sì ní san ẹran náà padà. 14“Bí ẹnìkan bá sì yá ẹranko lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, tí ẹranko náà sì fi ara pa, tàbí kí ó kú nígbà tí ẹni tí ó ni í kò sí nítòsí. O gbọdọ̀ san án padà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.