Eksodu 22:14
Exodus 22:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Bí ẹnìkan bá sì yá ẹranko lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, tí ẹranko náà sì fi ara pa, tàbí kí ó kú nígbà tí ẹni tí ó ni í kò sí nítòsí. O gbọdọ̀ san án padà.
Exodus 22:14 in English
Exodus 22:14 · Berean Standard Bible
If a man borrows an animal from his neighbor and it is injured or dies while its owner is not present, he must make full restitution.
Context
12Ṣùgbọ́n ti wọ́n bá jí ẹranko náà gbé ni ọ̀dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, yóò san ẹ̀san padà fún olúwa rẹ̀. 13Bí ẹranko búburú bá fà á ya, ó ní láti mú àyakù ẹran náà wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí, kò sì ní san ẹran náà padà. 14“Bí ẹnìkan bá sì yá ẹranko lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, tí ẹranko náà sì fi ara pa, tàbí kí ó kú nígbà tí ẹni tí ó ni í kò sí nítòsí. O gbọdọ̀ san án padà. 15Ṣùgbọ́n ti ó bá jẹ́ wí pé olóhun bá wà pẹ̀lú ẹranko náà, ẹni tí ó ya lò kò ní san ẹ̀san padà. Bí a bá yá ẹranko náà lò, owó tí ó fi yá a lò ni yóò fi tan àdánù ẹranko tí ó kú. 16“Bí ọkùnrin kan bá fi àrékérekè mú wúńdíá kan, ẹni tí kò pinnu láti fẹ́, tí ó sì bá a lòpọ̀, yóò san owó orí rẹ̀, yóò sì fi ṣe aya rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.