Native Bible

Exodus 18:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Inú Jetro dùn láti gbọ́ gbogbo ohun rere ti Olúwa ṣe fún Israẹli, ẹni tí ó mú wọ́n jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti.

Exodus 18:9 in English

Exodus 18:9 · Berean Standard Bible

And Jethro rejoiced over all the good things the LORD had done for Israel, whom He had rescued from the hand of the Egyptians.

Context

7Mose sì jáde lọ pàdé àna rẹ̀, ó tẹríba fún un, ó sì fi ẹnu kò ó ni ẹnu. Wọ́n sì béèrè àlàáfíà ara wọn, wọ́n sì wọ inú àgọ́ lọ. 8Mose sọ fún àna rẹ̀ nípa ohun gbogbo ti Olúwa tí ṣe sí Farao àti àwọn ará Ejibiti nítorí Israẹli. Ó sọ nípa gbogbo ìṣòro tí wọn bá pàdé ní ọ̀nà wọn àti bí Olúwa ti gbà wọ́n là. 9Inú Jetro dùn láti gbọ́ gbogbo ohun rere ti Olúwa ṣe fún Israẹli, ẹni tí ó mú wọ́n jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti. 10Jetro sì wí pé, “Ìyìn ni fún Olúwa, ẹni tí ó gba yín là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti àti lọ́wọ́ Farao, ẹni tí ó sì gba àwọn ènìyàn là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti. 11Mo mọ nísinsin yìí pé Olúwa tóbi ju gbogbo àwọn òrìṣà lọ; nítorí ti ó gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìgbéraga àti ìkà àwọn ará Ejibiti.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.