Native Bible

Exodus 18:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mose sì jáde lọ pàdé àna rẹ̀, ó tẹríba fún un, ó sì fi ẹnu kò ó ni ẹnu. Wọ́n sì béèrè àlàáfíà ara wọn, wọ́n sì wọ inú àgọ́ lọ.

Exodus 18:7 in English

Exodus 18:7 · Berean Standard Bible

So Moses went out to meet his father-in-law and bowed down and kissed him. They greeted each other and went into the tent.

Context

5Jetro, àna Mose, òun àti aya àti àwọn ọmọ Mose tọ̀ ọ́ wá nínú aginjù tí ó tẹ̀dó sí, nítòsí òkè Ọlọ́run. 6Jetro sì ti ránṣẹ́ sí Mose pé, “Èmi Jetro, àna rẹ, ni mo ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, èmi àti aya àti àwọn ọmọkùnrin rẹ méjèèjì.” 7Mose sì jáde lọ pàdé àna rẹ̀, ó tẹríba fún un, ó sì fi ẹnu kò ó ni ẹnu. Wọ́n sì béèrè àlàáfíà ara wọn, wọ́n sì wọ inú àgọ́ lọ. 8Mose sọ fún àna rẹ̀ nípa ohun gbogbo ti Olúwa tí ṣe sí Farao àti àwọn ará Ejibiti nítorí Israẹli. Ó sọ nípa gbogbo ìṣòro tí wọn bá pàdé ní ọ̀nà wọn àti bí Olúwa ti gbà wọ́n là. 9Inú Jetro dùn láti gbọ́ gbogbo ohun rere ti Olúwa ṣe fún Israẹli, ẹni tí ó mú wọ́n jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.