Native Bible

Exodus 18:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jetro sì ti ránṣẹ́ sí Mose pé, “Èmi Jetro, àna rẹ, ni mo ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, èmi àti aya àti àwọn ọmọkùnrin rẹ méjèèjì.”

Exodus 18:6 in English

Exodus 18:6 · Berean Standard Bible

He sent word to Moses, “I, your father-in-law Jethro, am coming to you with your wife and her two sons.”

Context

4Èkejì ń jẹ́ Elieseri; ó wí pé, “Ọlọ́run baba mi ni alátìlẹ́yìn mi, ó sì gbà mí là kúrò lọ́wọ́ idà Farao.” 5Jetro, àna Mose, òun àti aya àti àwọn ọmọ Mose tọ̀ ọ́ wá nínú aginjù tí ó tẹ̀dó sí, nítòsí òkè Ọlọ́run. 6Jetro sì ti ránṣẹ́ sí Mose pé, “Èmi Jetro, àna rẹ, ni mo ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, èmi àti aya àti àwọn ọmọkùnrin rẹ méjèèjì.” 7Mose sì jáde lọ pàdé àna rẹ̀, ó tẹríba fún un, ó sì fi ẹnu kò ó ni ẹnu. Wọ́n sì béèrè àlàáfíà ara wọn, wọ́n sì wọ inú àgọ́ lọ. 8Mose sọ fún àna rẹ̀ nípa ohun gbogbo ti Olúwa tí ṣe sí Farao àti àwọn ará Ejibiti nítorí Israẹli. Ó sọ nípa gbogbo ìṣòro tí wọn bá pàdé ní ọ̀nà wọn àti bí Olúwa ti gbà wọ́n là.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.