Eksodu 16:18
Exodus 16:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí wọ́n fi òsùwọ̀n omeri wọ̀n-ọ́n, ẹni tí ó kó púpọ̀ kò ní púpọ̀ jù, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó kó ìwọ̀nba kò ní kéré jù. Ẹnìkọ̀ọ̀kan kó ìwọ̀nba ti ó tó fún un.
Exodus 16:18 in English
Exodus 16:18 · Berean Standard Bible
When they measured it by the omer, he who gathered much had no excess, and he who gathered little had no shortfall.* Each one gathered as much as he needed to eat.
Context
16Èyí ni ohun tí Olúwa ti pàṣẹ, ‘Kí olúkúlùkù máa kó èyí ti ó tó fún un láti jẹ. Ẹ mú òsùwọ̀n omeri kan fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ti ó wà nínú àgọ́ yín.’ ” 17Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe bí a ti sọ fún wọn; àwọn kan kó púpọ̀, àwọn kan kó kékeré. 18Nígbà tí wọ́n fi òsùwọ̀n omeri wọ̀n-ọ́n, ẹni tí ó kó púpọ̀ kò ní púpọ̀ jù, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó kó ìwọ̀nba kò ní kéré jù. Ẹnìkọ̀ọ̀kan kó ìwọ̀nba ti ó tó fún un. 19Mose sì wí fún wọ́n pé, “Kí ẹnikẹ́ni ó má ṣe kó pamọ́ lára rẹ̀ di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì.” 20Ṣùgbọ́n, àwọn kan nínú wọn kò fetí sí Mose, wọ́n kó lára rẹ̀ pamọ́ di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ohun ti wọ́n kó pamọ́ kún fún ìdin, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní rùn. Nítorí náà Mose bínú sí wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.