Native Bible

Exodus 16:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n, àwọn kan nínú wọn kò fetí sí Mose, wọ́n kó lára rẹ̀ pamọ́ di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ohun ti wọ́n kó pamọ́ kún fún ìdin, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní rùn. Nítorí náà Mose bínú sí wọn.

Exodus 16:20 in English

Exodus 16:20 · Berean Standard Bible

But they did not listen to Moses; some people left part of it until morning, and it became infested with maggots and began to smell. So Moses was angry with them.

Context

18Nígbà tí wọ́n fi òsùwọ̀n omeri wọ̀n-ọ́n, ẹni tí ó kó púpọ̀ kò ní púpọ̀ jù, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó kó ìwọ̀nba kò ní kéré jù. Ẹnìkọ̀ọ̀kan kó ìwọ̀nba ti ó tó fún un. 19Mose sì wí fún wọ́n pé, “Kí ẹnikẹ́ni ó má ṣe kó pamọ́ lára rẹ̀ di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì.” 20Ṣùgbọ́n, àwọn kan nínú wọn kò fetí sí Mose, wọ́n kó lára rẹ̀ pamọ́ di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ohun ti wọ́n kó pamọ́ kún fún ìdin, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní rùn. Nítorí náà Mose bínú sí wọn. 21Ní òwúrọ̀, ni ojoojúmọ́ ni ẹnìkọ̀ọ̀kan ń lọ kó ìwọ̀nba ti ó tó fún un láti jẹ, bí oòrùn bá sì mú, a sì yọ́. 22Ní ọjọ́ kẹfà, wọ́n kó ìlọ́po méjì èyí tiwọn ń kó tẹ́lẹ̀: òsùwọ̀n omeri méjì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan; àwọn olórí ìjọ ènìyàn sì wá, wọ́n sì sọ èyí fún Mose.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.