Eksodu 15:5
Exodus 15:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ibú omi bò wọ́n mọ́lẹ̀; wọ́n sì rì sí ìsàlẹ̀ omi òkun bí òkúta.
Exodus 15:5 in English
Exodus 15:5 · Berean Standard Bible
The depths have covered them; they sank there like a stone.
Context
3Ológun ni Olúwa,
Olúwa ni orúkọ rẹ, 4kẹ̀kẹ́ ogun Farao àti ogun rẹ̀
ni ó mú wọ inú Òkun.
Àwọn ọmọ-ogun Farao tó jáfáfá jùlọ
ni ó rì sínú Òkun Pupa. 5Ibú omi bò wọ́n mọ́lẹ̀;
wọ́n sì rì sí ìsàlẹ̀ omi òkun bí òkúta. 6“Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa,
pọ̀ ní agbára.
Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa,
fọ́ àwọn ọ̀tá túútúú. 7“Nínú agbára ńlá rẹ ti ó tóbi
ìwọ bi àwọn ti ó dìde sí ọ ṣubú.
Ìwọ rán ìbínú gbígbóná rẹ;
tí ó run wọ́n bí àgémọ́lẹ̀ ìdí koríko.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.