Native Bible

Exodus 13:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ gbọdọ̀ pa òfin náà mọ́ ní àkókò tí a yàn bí ọdún tí ń gorí ọdún.

Exodus 13:10 in English

Exodus 13:10 · Berean Standard Bible

Therefore you shall keep this statute at the appointed time year after year.

Context

8Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin, ‘Mo ń ṣe èyí nítorí ohun tí Olúwa ṣe fún mi nígbà tí èmi jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti.’ 9Ṣíṣe èyí yóò wà fún àmì ní ọwọ́ rẹ, àti bí àmì ìrántí ni iwájú orí rẹ, tí yóò máa rán ọ létí òfin Olúwa ní ẹnu rẹ. Nítorí Olúwa mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá rẹ̀. 10Ìwọ gbọdọ̀ pa òfin náà mọ́ ní àkókò tí a yàn bí ọdún tí ń gorí ọdún. 11“Lẹ́yìn tí Olúwa tí mú ọ wá sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani tí ó sì fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ìlérí pẹ̀lú ìbúra fún ọ àti fún àwọn baba ńlá rẹ̀, 12ìwọ yóò fi àkọ́bí inú rẹ fún Olúwa. Gbogbo àkọ́bí ti ó jẹ́ akọ ti ẹran ọ̀sìn rẹ ní ó jẹ́ ti Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.