Esteri 9:12
Esther 9:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọba sì sọ fún Esteri ayaba pé, “Àwọn Júù ti pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ọkùnrin àti àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí i ṣe ọmọ Hamani ní ilé ìṣọ́ Susa run. Kí ni wọ́n ṣe ní gbogbo ìgbèríko ọba tókù? Báyìí kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó fi fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ? A ó sì tún fi fún ọ.”
Esther 9:12 in English
Esther 9:12 · Berean Standard Bible
who said to Queen Esther, “In the citadel of Susa the Jews have killed and destroyed five hundred men, including Haman’s ten sons. What have they done in the rest of the royal provinces? Now what is your petition? It will be given to you. And what further do you request? It will be fulfilled.”
Context
10Àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí wọ́n jẹ́ ọmọ Hamani, ọmọ Hammedata, ọ̀tá àwọn Júù. Ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ wọn lé ìkógun un wọn. 11Ní ọjọ́ náà gan an ni a mú iye àwọn tí a pa ní ilé ìṣọ́ ti Susa wá fún ọba. 12Ọba sì sọ fún Esteri ayaba pé, “Àwọn Júù ti pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ọkùnrin àti àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí i ṣe ọmọ Hamani ní ilé ìṣọ́ Susa run. Kí ni wọ́n ṣe ní gbogbo ìgbèríko ọba tókù? Báyìí kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó fi fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ? A ó sì tún fi fún ọ.” 13Esteri sì dáhùn pé, “Bí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, fún àwọn Júù tí ó wà ní Susa ní àṣẹ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní òní kí wọn ṣe bákan náà ní ọ̀la, kí a sì so àwọn ọmọkùnrin Hamani mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà rọ̀ sórí igi.” 14Nítorí náà ọba pàṣẹ pé kí a ṣe bẹ́ẹ̀. A sì gbé àṣẹ kan jáde ní Susa, wọ́n sì so àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá Hamani kọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.