Esteri 9:10
Esther 9:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí wọ́n jẹ́ ọmọ Hamani, ọmọ Hammedata, ọ̀tá àwọn Júù. Ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ wọn lé ìkógun un wọn.
Esther 9:10 in English
Esther 9:10 · Berean Standard Bible
They killed these ten sons of Haman son of Hammedatha, the enemy of the Jews, but they did not lay a hand on the plunder.
Context
8Porata, Adalia, Aridata, 9Parmaṣta, Arisai, Aridai àti Faisata. 10Àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí wọ́n jẹ́ ọmọ Hamani, ọmọ Hammedata, ọ̀tá àwọn Júù. Ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ wọn lé ìkógun un wọn. 11Ní ọjọ́ náà gan an ni a mú iye àwọn tí a pa ní ilé ìṣọ́ ti Susa wá fún ọba. 12Ọba sì sọ fún Esteri ayaba pé, “Àwọn Júù ti pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ọkùnrin àti àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí i ṣe ọmọ Hamani ní ilé ìṣọ́ Susa run. Kí ni wọ́n ṣe ní gbogbo ìgbèríko ọba tókù? Báyìí kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó fi fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ? A ó sì tún fi fún ọ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.