Esteri 7:2
Esther 7:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
bí wọ́n sì ṣe ń mu wáìnì ní ọjọ́ kejì yìí, ọba sì tún béèrè pé, “Esteri ayaba, kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó sì fi fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ ìdajì ìjọba à mi, n ó fi fún ọ.”
Esther 7:2 in English
Esther 7:2 · Berean Standard Bible
and as they drank their wine on that second day, the king asked once more, “Queen Esther, what is your petition? It will be given to you. What is your request? Even up to half the kingdom, it will be fulfilled.”
Context
1Ọba àti Hamani sì lọ sí àpèjẹ pẹ̀lú Esteri ayaba, 2bí wọ́n sì ṣe ń mu wáìnì ní ọjọ́ kejì yìí, ọba sì tún béèrè pé, “Esteri ayaba, kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó sì fi fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ ìdajì ìjọba à mi, n ó fi fún ọ.” 3Nígbà náà ni ayaba Esteri dáhùn, “Bí èmi bá rí ojúrere rẹ, ìwọ ọba, bí ó bá sì tẹ́ ọláńlá à rẹ lọ́rùn, fún mi ní ẹ̀mí mi, èyí ni ẹ̀bẹ̀ mi. Kí o sì pa àwọn ènìyàn mi mọ́—èyí ni ìbéèrè mi. 4Nítorí a ti ta èmi àti àwọn ènìyàn mi fún àwọn tí yóò pa wá run, à ti ṣe ìdájọ́ wa fún pípa àti píparẹ́. Bí a bá tilẹ̀ tà wá bí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ǹ bá dákẹ́, nítorí irú ìpọ́njú bẹ́ẹ̀ kò tó èyí tí à ń yọ ọba lẹ́nu sí.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.