Esteri 6:5
Esther 6:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dáhùn pé, “Hamani ni ó wà níbẹ̀ ó dúró sí inú àgbàlá.” Ọba pàṣẹ pé, “Ẹ mú un wọlé wá.”
Esther 6:5 in English
Esther 6:5 · Berean Standard Bible
So the king’s attendants answered him, “Haman is there, standing in the court.” “Bring him in,” ordered the king.
Context
3Ọba béèrè pé, “Kí ni ọlá àti iyì tí Mordekai ti gbà fún èyí?”
Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dáhùn pé, “Kò tí ì sí ohun tí a ṣe fún un.” 4Ọba wí pé, “Ta ni ó wà nínú àgbàlá?” Nísinsin yìí, Hamani ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ àgbàlá ìta ààfin ni láti sọ fún ọba nípa síso Mordekai lórí igi tí ó ti rì fún un. 5Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dáhùn pé, “Hamani ni ó wà níbẹ̀ ó dúró sí inú àgbàlá.”
Ọba pàṣẹ pé, “Ẹ mú un wọlé wá.” 6Nígbà tí Hamani wọlé, ọba béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni kí a ṣe fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti bu ọlá fún?”
Nísinsin yìí Hamani sì ro èyí fúnra rẹ̀ pé, “Ta ni ó wà níbẹ̀ tí ọba fẹ́ dá lọ́lá ju èmi lọ?” 7Nítorí náà Hamani dá ọba lóhùn pé, “Fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.