Esteri 6:3
Esther 6:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọba béèrè pé, “Kí ni ọlá àti iyì tí Mordekai ti gbà fún èyí?” Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dáhùn pé, “Kò tí ì sí ohun tí a ṣe fún un.”
Esther 6:3 in English
Esther 6:3 · Berean Standard Bible
The king inquired, “What honor or dignity has been bestowed on Mordecai for this act?” “Nothing has been done for him,” replied the king’s attendants.
Context
1Ní òru ọjọ́ náà ọba kò le è sùn; nítorí náà, ó pàṣẹ kí wọn mú ìwé ìrántí wá, àkọsílẹ̀ ìjọba rẹ̀, wọ́n mú un wá wọ́n sì kà á sí létí. 2Wọ́n rí àkọsílẹ̀ níbẹ̀ pé Mordekai tí sọ àṣírí Bigitana àti Tereṣi, àwọn ìjòyè ọba méjì tí wọ́n ń ṣọ́ ẹnu-ọ̀nà, tí wọ́n ń gbèrò láti pa ọba Ahaswerusi. 3Ọba béèrè pé, “Kí ni ọlá àti iyì tí Mordekai ti gbà fún èyí?”
Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dáhùn pé, “Kò tí ì sí ohun tí a ṣe fún un.” 4Ọba wí pé, “Ta ni ó wà nínú àgbàlá?” Nísinsin yìí, Hamani ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ àgbàlá ìta ààfin ni láti sọ fún ọba nípa síso Mordekai lórí igi tí ó ti rì fún un. 5Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dáhùn pé, “Hamani ni ó wà níbẹ̀ ó dúró sí inú àgbàlá.”
Ọba pàṣẹ pé, “Ẹ mú un wọlé wá.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.