Efesu 6:11
Ephesians 6:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè kọ ojú ìjà sí àrékérekè èṣù.
Ephesians 6:11 in English
Ephesians 6:11 · Berean Standard Bible
Put on the full armor of God, so that you can make your stand against the devil’s schemes.
Context
9Àti ẹ̀yin ọ̀gá, ẹ máa ṣe irú ìtọ́jú kan náà sí àwọn ẹrú yin, ẹ máa dín ìbẹ̀rù yín kù bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé Olúwa ẹ̀yin tìkára yín ń bẹ ní ọ̀run; kò sì ṣí ojúsàájú ènìyàn lọ́dọ̀ rẹ̀. 10Ní àkótán, ara mí, ẹ jẹ́ alágbára nínú Olúwa, àti nínú agbára ipá rẹ̀. 11Ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè kọ ojú ìjà sí àrékérekè èṣù. 12Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara ní àwa ń bá jìjàkadì, ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè, àwọn ọlọ́lá, àwọn aláṣẹ ìbí òkùnkùn ayé yìí, àti àwọn ẹ̀mí búburú ní ojú ọ̀run. 13Nítorí náà, ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè dúró tiiri sí ọjọ́ ibi, nígbà tí ẹ̀yin bá sì ti ṣe ohun gbogbo tan kí ẹ sì dúró.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.