Oniwaasu 7:27
Ecclesiastes 7:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Oniwaasu wí pé, “Wò ó, eléyìí ni ohun tí mo ti ṣàwárí: “Mímú ohun kan pọ̀ mọ́ òmíràn láti ṣàwárí ìdí ohun gbogbo.
Ecclesiastes 7:27 in English
Ecclesiastes 7:27 · Berean Standard Bible
“Behold,” says the Teacher, “I have discovered this by adding one thing to another to find an explanation.
Context
25Mo wá rò ó nínú ọkàn mi láti mọ̀,
láti wá àti láti ṣàwárí ọgbọ́n
àti ìdí ohun gbogbo, àti láti mọ ìwà àgọ́
búburú àti ti ìsínwín tàbí òmùgọ̀. 26Mo rí ohun tí ó korò ju ikú lọ
obìnrin tí ó jẹ́ ẹ̀bìtì,
tí ọkàn rẹ̀ jẹ́ tàkúté
tí ọwọ́ rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀wọ̀n,
ọkùnrin tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn yóò le è yọ sílẹ̀
ṣùgbọ́n ẹni dẹ́ṣẹ̀ kò le è bọ́ nínú tàkúté rẹ̀. 27Oniwaasu wí pé, “Wò ó, eléyìí ni ohun tí mo ti ṣàwárí:
“Mímú ohun kan pọ̀ mọ́ òmíràn láti ṣàwárí ìdí ohun gbogbo. 28Nígbà tí mo sì ń wá a kiri
ṣùgbọ́n tí n kò rí i
mo rí ọkùnrin tí ó dúró dáradára kan láàrín ẹgbẹ̀rún (1,000),
ṣùgbọ́n n kò rí obìnrin,
kankan kí ó dúró láàrín gbogbo wọn. 29Eléyìí nìkan ni mo tí ì rí:
Ọlọ́run dá ìran ènìyàn dáradára,
ṣùgbọ́n ènìyàn ti lọ láti ṣàwárí ohun púpọ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.