Oniwaasu 7:16
Ecclesiastes 7:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Má ṣe jẹ́ olódodo jùlọ tàbí ọlọ́gbọ́n jùlọ kí ló dé tí o fi fẹ́ pa ara rẹ run?
Ecclesiastes 7:16 in English
Ecclesiastes 7:16 · Berean Standard Bible
Do not be overly righteous, and do not make yourself too wise. Why should you destroy yourself?
Context
14Nígbà tí àkókò bá dára, jẹ́ kí inú rẹ dùn,
ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kò bá dára, rò ó:
Ọlọ́run tí ó dá èkínní
náà ni ó dá èkejì.
Nítorí náà, ènìyàn kò le è ṣàwárí
ohun kankan nípa ọjọ́ iwájú rẹ̀. 15Nínú ayé àìní ìtumọ̀ yìí ni mo ti rí gbogbo èyí
ènìyàn olóòtítọ́, ọkùnrin olódodo ń parun nínú òtítọ́ rẹ̀
ìkà ènìyàn sì ń gbé ìgbé ayé pípẹ́ nínú ìkà rẹ̀. 16Má ṣe jẹ́ olódodo jùlọ
tàbí ọlọ́gbọ́n jùlọ
kí ló dé tí o fi fẹ́ pa ara rẹ run? 17Ìwọ ma ṣe búburú jùlọ kí ìwọ má sì ṣe aṣiwèrè,
èéṣe tí ìwọ yóò fi kú kí ọjọ́ rẹ tó pé 18Ó dára láti mú ọ̀kan
kí o má sì ṣe fi èkejì sílẹ̀.
Ọkùnrin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run yóò bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àrékérekè.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.