Oniwaasu 7:14
Ecclesiastes 7:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí àkókò bá dára, jẹ́ kí inú rẹ dùn, ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kò bá dára, rò ó: Ọlọ́run tí ó dá èkínní náà ni ó dá èkejì. Nítorí náà, ènìyàn kò le è ṣàwárí ohun kankan nípa ọjọ́ iwájú rẹ̀.
Ecclesiastes 7:14 in English
Ecclesiastes 7:14 · Berean Standard Bible
In the day of prosperity, be joyful, but in the day of adversity, consider this: God has made one of these along with the other, so that a man cannot discover anything that will come after him.
Context
12Ọgbọ́n jẹ́ ààbò
gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ ààbò
ṣùgbọ́n àǹfààní òye ni èyí
pé ọgbọ́n a máa tọ́jú ẹ̀mí ẹni tí ó bá ní. 13Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe:
“Ta ni ó le è to
ohun tí ó ti ṣe ní wíwọ́?” 14Nígbà tí àkókò bá dára, jẹ́ kí inú rẹ dùn,
ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kò bá dára, rò ó:
Ọlọ́run tí ó dá èkínní
náà ni ó dá èkejì.
Nítorí náà, ènìyàn kò le è ṣàwárí
ohun kankan nípa ọjọ́ iwájú rẹ̀. 15Nínú ayé àìní ìtumọ̀ yìí ni mo ti rí gbogbo èyí
ènìyàn olóòtítọ́, ọkùnrin olódodo ń parun nínú òtítọ́ rẹ̀
ìkà ènìyàn sì ń gbé ìgbé ayé pípẹ́ nínú ìkà rẹ̀. 16Má ṣe jẹ́ olódodo jùlọ
tàbí ọlọ́gbọ́n jùlọ
kí ló dé tí o fi fẹ́ pa ara rẹ run?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.