Oniwaasu 6:11
Ecclesiastes 6:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọ̀rọ̀ púpọ̀, kì í ní ìtumọ̀ èrè wo ni ènìyàn ń rí nínú rẹ̀?
Ecclesiastes 6:11 in English
Ecclesiastes 6:11 · Berean Standard Bible
For the more words, the more futility—and how does that profit anyone?
Context
9Ohun tí ojú rí sàn
ju ìfẹnuwákiri lọ.
Asán ni eléyìí pẹ̀lú
ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́. 10Ohunkóhun tí ó bá ti wà ti ní orúkọ,
ohun tí ènìyàn jẹ́ sì ti di mí mọ̀;
kò sí ènìyàn tí ó le è ja ìjàkadì
pẹ̀lú ẹni tí ó lágbára jù ú lọ. 11Ọ̀rọ̀ púpọ̀,
kì í ní ìtumọ̀
èrè wo ni ènìyàn ń rí nínú rẹ̀? 12Àbí, ta ni ó mọ ohun tí ó dára fún ènìyàn ní ayé fún ọjọ́ ayé kúkúrú àti asán tí ó ń là kọjá gẹ́gẹ́ bí òjìji? Ta ni ó le è sọ fún mi, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn lẹ́yìn tí ó bá lọ tán? Kò sí!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.