Native Bible

Ecclesiastes 6:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àbí, ta ni ó mọ ohun tí ó dára fún ènìyàn ní ayé fún ọjọ́ ayé kúkúrú àti asán tí ó ń là kọjá gẹ́gẹ́ bí òjìji? Ta ni ó le è sọ fún mi, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn lẹ́yìn tí ó bá lọ tán? Kò sí!

Ecclesiastes 6:12 in English

Ecclesiastes 6:12 · Berean Standard Bible

For who knows what is good for a man during the few days in which he passes through his fleeting life like a shadow? Who can tell a man what will come after him under the sun?

Context

10Ohunkóhun tí ó bá ti wà ti ní orúkọ, ohun tí ènìyàn jẹ́ sì ti di mí mọ̀; kò sí ènìyàn tí ó le è ja ìjàkadì pẹ̀lú ẹni tí ó lágbára jù ú lọ. 11Ọ̀rọ̀ púpọ̀, kì í ní ìtumọ̀ èrè wo ni ènìyàn ń rí nínú rẹ̀? 12Àbí, ta ni ó mọ ohun tí ó dára fún ènìyàn ní ayé fún ọjọ́ ayé kúkúrú àti asán tí ó ń là kọjá gẹ́gẹ́ bí òjìji? Ta ni ó le è sọ fún mi, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn lẹ́yìn tí ó bá lọ tán? Kò sí!

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.