Oniwaasu 2:4
Ecclesiastes 2:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo ṣe àwọn iṣẹ́ ńlá ńlá. Mo kọ́ ilé púpọ̀ fún ara mi, mo sì gbin ọgbà àjàrà púpọ̀.
Ecclesiastes 2:4 in English
Ecclesiastes 2:4 · Berean Standard Bible
I expanded my pursuits. I built houses and planted vineyards for myself.
Context
2“Mo wí fún ẹ̀rín pé òmùgọ̀ ni. Àti fún ìre-ayọ̀ pé kí ni ó ń ṣe?” 3Mo tiraka láti dun ara mi nínú pẹ̀lú ọtí wáìnì, àti láti fi ọwọ́ lé òmùgọ̀—ọkàn mi sì ń tọ́ mi pẹ̀lú ọgbọ́n. Mo fẹ́ wo ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe fún ènìyàn ní abẹ́ ọ̀run ní ìwọ̀nba ọjọ́ ayé rẹ̀. 4Mo ṣe àwọn iṣẹ́ ńlá ńlá. Mo kọ́ ilé púpọ̀ fún ara mi, mo sì gbin ọgbà àjàrà púpọ̀. 5Mo ṣe ọgbà àti àgbàlá, mo sì gbin onírúurú igi eléso sí inú wọn. 6Mo gbẹ́ adágún láti máa bu omi rin àwọn igi tí ó ń hù jáde nínú ọgbà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.