Oniwaasu 10:5
Ecclesiastes 10:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ohun ibi kan wà tí mo ti rí lábẹ́ oòrùn, irú àṣìṣe tí ó dìde láti ọ̀dọ̀ alákòóso.
Ecclesiastes 10:5 in English
Ecclesiastes 10:5 · Berean Standard Bible
There is an evil I have seen under the sun— an error that proceeds from the ruler:
Context
3Kódà bí ó ti ṣe ń rìn láàrín ọ̀nà,
òmùgọ̀ kò ní ọgbọ́n
a sì máa fihan gbogbo ènìyàn bí ó ti gọ̀ tó. 4Bí ìbínú alákòóso bá dìde lòdì sí ọ,
ma ṣe fi ààyè rẹ sílẹ̀;
ìdákẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ le è tú àṣìṣe ńlá. 5Ohun ibi kan wà tí mo ti rí lábẹ́ oòrùn,
irú àṣìṣe tí ó dìde láti ọ̀dọ̀ alákòóso. 6A gbé aṣiwèrè sí ọ̀pọ̀ ipò tí ó ga jùlọ,
nígbà tí ọlọ́rọ̀ gba àwọn ààyè tí ó kéré jùlọ. 7Mo ti rí ẹrú lórí ẹṣin,
nígbà tí ọmọ-aládé ń fi ẹsẹ̀ rìn bí ẹrú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.