Oniwaasu 10:3
Ecclesiastes 10:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kódà bí ó ti ṣe ń rìn láàrín ọ̀nà, òmùgọ̀ kò ní ọgbọ́n a sì máa fihan gbogbo ènìyàn bí ó ti gọ̀ tó.
Ecclesiastes 10:3 in English
Ecclesiastes 10:3 · Berean Standard Bible
Even as the fool walks along the road, his sense is lacking, and he shows everyone that he is a fool.
Context
1Gẹ́gẹ́ bí òkú eṣinṣin tí ń fún òróró ìkunra ní òórùn búburú,
bẹ́ẹ̀ náà ni òmùgọ̀ díẹ̀ ṣe ń bo ọgbọ́n àti ọlá mọ́lẹ̀. 2Ọkàn ọlọ́gbọ́n a máa ṣí sí ohun tí ó tọ̀nà,
ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ sí ohun tí kò dára. 3Kódà bí ó ti ṣe ń rìn láàrín ọ̀nà,
òmùgọ̀ kò ní ọgbọ́n
a sì máa fihan gbogbo ènìyàn bí ó ti gọ̀ tó. 4Bí ìbínú alákòóso bá dìde lòdì sí ọ,
ma ṣe fi ààyè rẹ sílẹ̀;
ìdákẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ le è tú àṣìṣe ńlá. 5Ohun ibi kan wà tí mo ti rí lábẹ́ oòrùn,
irú àṣìṣe tí ó dìde láti ọ̀dọ̀ alákòóso.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.