Native Bible

Deuteronomy 9:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí Olúwa ran an yín jáde ní Kadeṣi-Barnea, Ó wí pé, “Ẹ gòkè lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín.” Ṣùgbọ́n ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí òfin Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ kò gbẹ́kẹ̀lé e, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọ́ tirẹ̀.

Deuteronomy 9:23 in English

Deuteronomy 9:23 · Berean Standard Bible

And when the LORD sent you out from Kadesh-barnea, He said, “Go up and possess the land that I have given you.” But you rebelled against the command of the LORD your God. You neither believed Him nor obeyed Him.

Context

21Bẹ́ẹ̀ ni mo sì mú ohun tí ó mú un yín dẹ́ṣẹ̀, àní ère ẹgbọrọ màlúù tí ẹ ti ṣe, mo sì fi iná sun ún, bẹ́ẹ̀ ni mo gún un, mo sì lọ̀ ọ́ lúúlúú bí eruku lẹ́búlẹ́bú, mo sì da ẹ̀lọ̀ rẹ̀ sínú odò tí ń sàn nísàlẹ̀ òkè. 22Ẹ̀yin tún mú Olúwa bínú ní Tabera, Massa àti ní Kibirotu-Hattaafa. 23Nígbà tí Olúwa ran an yín jáde ní Kadeṣi-Barnea, Ó wí pé, “Ẹ gòkè lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín.” Ṣùgbọ́n ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí òfin Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ kò gbẹ́kẹ̀lé e, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọ́ tirẹ̀. 24Láti ìgbà tí mo ti mọ̀ yín ni ẹ ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa. 25Mo ti wólẹ̀ níwájú Olúwa fún ogójì ọ̀sán àti òru wọ̀nyí nítorí pé Olúwa sọ pé Òun yóò pa yín run.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.