Deuteronomi 9:21
Deuteronomy 9:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bẹ́ẹ̀ ni mo sì mú ohun tí ó mú un yín dẹ́ṣẹ̀, àní ère ẹgbọrọ màlúù tí ẹ ti ṣe, mo sì fi iná sun ún, bẹ́ẹ̀ ni mo gún un, mo sì lọ̀ ọ́ lúúlúú bí eruku lẹ́búlẹ́bú, mo sì da ẹ̀lọ̀ rẹ̀ sínú odò tí ń sàn nísàlẹ̀ òkè.
Deuteronomy 9:21 in English
Deuteronomy 9:21 · Berean Standard Bible
And I took that sinful thing, the calf you had made, and burned it in the fire. Then I crushed it and ground it to powder as fine as dust, and I cast it into the stream that came down from the mountain.
Context
19Mo bẹ̀rù ìbínú àti ìrunú Olúwa, nítorí pé inú bí i sí i yín dé bi wí pé ó fẹ́ pa yín run. Ṣùgbọ́n Olúwa tún fetí sí mi lẹ́ẹ̀kan sí i. 20Inú sì bí Olúwa sí Aaroni láti pa á run, nígbà náà ni mo tún gbàdúrà fún Aaroni náà. 21Bẹ́ẹ̀ ni mo sì mú ohun tí ó mú un yín dẹ́ṣẹ̀, àní ère ẹgbọrọ màlúù tí ẹ ti ṣe, mo sì fi iná sun ún, bẹ́ẹ̀ ni mo gún un, mo sì lọ̀ ọ́ lúúlúú bí eruku lẹ́búlẹ́bú, mo sì da ẹ̀lọ̀ rẹ̀ sínú odò tí ń sàn nísàlẹ̀ òkè. 22Ẹ̀yin tún mú Olúwa bínú ní Tabera, Massa àti ní Kibirotu-Hattaafa. 23Nígbà tí Olúwa ran an yín jáde ní Kadeṣi-Barnea, Ó wí pé, “Ẹ gòkè lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín.” Ṣùgbọ́n ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí òfin Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ kò gbẹ́kẹ̀lé e, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọ́ tirẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.