Deuteronomi 9:25
Deuteronomy 9:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo ti wólẹ̀ níwájú Olúwa fún ogójì ọ̀sán àti òru wọ̀nyí nítorí pé Olúwa sọ pé Òun yóò pa yín run.
Deuteronomy 9:25 in English
Deuteronomy 9:25 · Berean Standard Bible
So I fell down before the LORD for forty days and forty nights, because the LORD had said He would destroy you.
Context
23Nígbà tí Olúwa ran an yín jáde ní Kadeṣi-Barnea, Ó wí pé, “Ẹ gòkè lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín.” Ṣùgbọ́n ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí òfin Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ kò gbẹ́kẹ̀lé e, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọ́ tirẹ̀. 24Láti ìgbà tí mo ti mọ̀ yín ni ẹ ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa. 25Mo ti wólẹ̀ níwájú Olúwa fún ogójì ọ̀sán àti òru wọ̀nyí nítorí pé Olúwa sọ pé Òun yóò pa yín run. 26Mo gbàdúrà sí Olúwa wí pé, “Olúwa Olódùmarè, má ṣe run àwọn ènìyàn rẹ, àní ogún rẹ tí o ti rà padà, nípa agbára rẹ tí o sì fi agbára ńlá mú wọn jáde láti Ejibiti wá. 27Rántí àwọn ìránṣẹ́ rẹ Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu. Fojú fo orí kunkun àwọn ènìyàn yìí, pẹ̀lú ìwà búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.