Deuteronomi 9:16
Deuteronomy 9:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìgbà tí mo ṣàkíyèsí, mo rí i pé ẹ ti dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ ti ṣe ère òrìṣà ní ìrí ọ̀dọ́ màlúù, fún ara yín. Ẹ ti yípadà kánkán kúrò nínú ọ̀nà tí Olúwa ti pàṣẹ fún un yín.
Deuteronomy 9:16 in English
Deuteronomy 9:16 · Berean Standard Bible
And I saw how you had sinned against the LORD your God; you had made for yourselves a molten calf. You had turned aside quickly from the way that the LORD had commanded you.
Context
14Fi mí sílẹ̀, jẹ́ kí n run wọ́n, kí n sì pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run. Èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè tí ó lágbára tí ó sì pọ̀jù wọ́n lọ.” 15Báyìí ni mo yípadà, tí mó sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà wá, orí òkè tí o ń yọ iná. Àwọn wàláà májẹ̀mú méjèèjì sì wà lọ́wọ́ mi. 16Ìgbà tí mo ṣàkíyèsí, mo rí i pé ẹ ti dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ ti ṣe ère òrìṣà ní ìrí ọ̀dọ́ màlúù, fún ara yín. Ẹ ti yípadà kánkán kúrò nínú ọ̀nà tí Olúwa ti pàṣẹ fún un yín. 17Bẹ́ẹ̀ ni mó ju wàláà méjèèjì náà mọ́lẹ̀, mo sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ lójú u yín. 18Lẹ́yìn náà mo tún wólẹ̀ níwájú Olúwa fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, èmi kò jẹ oúnjẹ kankan bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mu omi, nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ tí dá, tí ẹ sì ń ṣe búburú lójú Olúwa, tí ẹ sì ń mú u bínú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.