Native Bible

Deuteronomy 9:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ni mó ju wàláà méjèèjì náà mọ́lẹ̀, mo sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ lójú u yín.

Deuteronomy 9:17 in English

Deuteronomy 9:17 · Berean Standard Bible

So I took the two tablets and threw them out of my hands, shattering them before your eyes.

Context

15Báyìí ni mo yípadà, tí mó sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà wá, orí òkè tí o ń yọ iná. Àwọn wàláà májẹ̀mú méjèèjì sì wà lọ́wọ́ mi. 16Ìgbà tí mo ṣàkíyèsí, mo rí i pé ẹ ti dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ ti ṣe ère òrìṣà ní ìrí ọ̀dọ́ màlúù, fún ara yín. Ẹ ti yípadà kánkán kúrò nínú ọ̀nà tí Olúwa ti pàṣẹ fún un yín. 17Bẹ́ẹ̀ ni mó ju wàláà méjèèjì náà mọ́lẹ̀, mo sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ lójú u yín. 18Lẹ́yìn náà mo tún wólẹ̀ níwájú Olúwa fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, èmi kò jẹ oúnjẹ kankan bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mu omi, nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ tí dá, tí ẹ sì ń ṣe búburú lójú Olúwa, tí ẹ sì ń mú u bínú. 19Mo bẹ̀rù ìbínú àti ìrunú Olúwa, nítorí pé inú bí i sí i yín dé bi wí pé ó fẹ́ pa yín run. Ṣùgbọ́n Olúwa tún fetí sí mi lẹ́ẹ̀kan sí i.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.