Native Bible

Deuteronomy 7:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, ẹ rántí dáradára ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín ṣe sí Farao àti gbogbo Ejibiti.

Deuteronomy 7:18 in English

Deuteronomy 7:18 · Berean Standard Bible

But do not be afraid of them. Be sure to remember what the LORD your God did to Pharaoh and all Egypt:

Context

16Gbogbo àwọn ènìyàn tí Olúwa Ọlọ́run yín fi lé yín lọ́wọ́ ni kí ẹ parun pátápátá. Ẹ má ṣe ṣàánú fún wọn, ẹ má ṣe sin olúwa ọlọ́run wọn torí pé ìdánwò ni èyí jẹ́ fún un yín. 17Ẹ lè máa rò láàrín ara yín pé, “Àwọn orílẹ̀-èdè yìí lágbára jù wá lọ. Báwo ni a o ṣe lé wọn jáde?” 18Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, ẹ rántí dáradára ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín ṣe sí Farao àti gbogbo Ejibiti. 19Ẹ sá à fi ojú u yín rí àwọn àdánwò ńlá, àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá, ọwọ́ agbára àti nínà ọwọ́ tí Olúwa Ọlọ́run yín fi mú un yín jáde. Olúwa Ọlọ́run yín yóò ṣe bákan náà sí gbogbo àwọn ènìyàn náà tí ẹ ń bẹ̀rù. 20Pẹ̀lúpẹ̀lú, Olúwa Ọlọ́run yín yóò rán oyin sáàrín wọn títí tí àwọn tí ó sálà tí wọ́n sá pamọ́ fún un yín, yóò fi ṣègbé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.