Deuteronomi 7:17
Deuteronomy 7:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ lè máa rò láàrín ara yín pé, “Àwọn orílẹ̀-èdè yìí lágbára jù wá lọ. Báwo ni a o ṣe lé wọn jáde?”
Deuteronomy 7:17 in English
Deuteronomy 7:17 · Berean Standard Bible
You may say in your heart, “These nations are greater than we are; how can we drive them out?”
Context
15Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ààrùn gbogbo, kì yóò jẹ́ kí èyíkéyìí ààrùn búburú tí ẹ mọ̀ ní Ejibiti wá sára yín, ṣùgbọ́n yóò fi wọ́n lé ara gbogbo àwọn tí ó kórìíra yín. 16Gbogbo àwọn ènìyàn tí Olúwa Ọlọ́run yín fi lé yín lọ́wọ́ ni kí ẹ parun pátápátá. Ẹ má ṣe ṣàánú fún wọn, ẹ má ṣe sin olúwa ọlọ́run wọn torí pé ìdánwò ni èyí jẹ́ fún un yín. 17Ẹ lè máa rò láàrín ara yín pé, “Àwọn orílẹ̀-èdè yìí lágbára jù wá lọ. Báwo ni a o ṣe lé wọn jáde?” 18Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, ẹ rántí dáradára ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín ṣe sí Farao àti gbogbo Ejibiti. 19Ẹ sá à fi ojú u yín rí àwọn àdánwò ńlá, àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá, ọwọ́ agbára àti nínà ọwọ́ tí Olúwa Ọlọ́run yín fi mú un yín jáde. Olúwa Ọlọ́run yín yóò ṣe bákan náà sí gbogbo àwọn ènìyàn náà tí ẹ ń bẹ̀rù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.