Deuteronomi 7:11
Deuteronomy 7:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà ẹ kíyèsi láti máa tẹ̀lé àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin tí mo fun un yín lónìí.
Deuteronomy 7:11 in English
Deuteronomy 7:11 · Berean Standard Bible
So keep the commandments and statutes and ordinances that I am giving you to follow this day.
Context
9Nítorí náà ẹ mọ̀ dájúdájú pé Olúwa Ọlọ́run yín, Òun ni Ọlọ́run, Ọlọ́run olóòtítọ́ ni, tí ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìran, àwọn tí ó fẹ́ ẹ tí ó sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. 10Ṣùgbọ́n
àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ ni yóò san ẹ̀san fún ní gbangba nípa pípa wọ́n run;
kì yóò sì jáfara láti san ẹ̀san fún àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ ní gbangba. 11Nítorí náà ẹ kíyèsi láti máa tẹ̀lé àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin tí mo fun un yín lónìí. 12Bí ẹ bá ń kíyèsi àwọn òfin wọ̀nyí tí ẹ sì ń ṣọ́ra láti ṣe wọ́n, nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run yín yóò pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ fún un yín, bí ó ti búra fún àwọn baba ńlá a yín. 13Yóò fẹ́ràn yín, yóò bùkún un yín yóò sì mú kí ẹ pọ̀ sí i. Yóò bùkún èso inú yín, ọ̀gbìn ilẹ̀ yín, oúnjẹ yín, wáìnì tuntun àti òróró yín, àwọn màlúù, agbo ẹran yín, àti àwọn àgùntàn, ọ̀wọ́ ẹran yín, ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá yín láti fún un yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.