Native Bible

Deuteronomy 7:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Yóò fẹ́ràn yín, yóò bùkún un yín yóò sì mú kí ẹ pọ̀ sí i. Yóò bùkún èso inú yín, ọ̀gbìn ilẹ̀ yín, oúnjẹ yín, wáìnì tuntun àti òróró yín, àwọn màlúù, agbo ẹran yín, àti àwọn àgùntàn, ọ̀wọ́ ẹran yín, ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá yín láti fún un yín.

Deuteronomy 7:13 in English

Deuteronomy 7:13 · Berean Standard Bible

He will love you and bless you and multiply you. He will bless the fruit of your womb and the produce of your land—your grain, new wine, and oil, the young of your herds and the lambs of your flocks—in the land that He swore to your fathers to give you.

Context

11Nítorí náà ẹ kíyèsi láti máa tẹ̀lé àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin tí mo fun un yín lónìí. 12Bí ẹ bá ń kíyèsi àwọn òfin wọ̀nyí tí ẹ sì ń ṣọ́ra láti ṣe wọ́n, nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run yín yóò pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ fún un yín, bí ó ti búra fún àwọn baba ńlá a yín. 13Yóò fẹ́ràn yín, yóò bùkún un yín yóò sì mú kí ẹ pọ̀ sí i. Yóò bùkún èso inú yín, ọ̀gbìn ilẹ̀ yín, oúnjẹ yín, wáìnì tuntun àti òróró yín, àwọn màlúù, agbo ẹran yín, àti àwọn àgùntàn, ọ̀wọ́ ẹran yín, ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá yín láti fún un yín. 14A ó bùkún un yín ju gbogbo ènìyàn lọ, kò sí ẹni tí yóò yàgàn nínú ọkùnrin tàbí obìnrin yín, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ọ̀kan nínú àwọn ohun ọ̀sìn in yín tí yóò wà láìlọ́mọ. 15Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ààrùn gbogbo, kì yóò jẹ́ kí èyíkéyìí ààrùn búburú tí ẹ mọ̀ ní Ejibiti wá sára yín, ṣùgbọ́n yóò fi wọ́n lé ara gbogbo àwọn tí ó kórìíra yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.