Native Bible

Deuteronomy 6:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ.

Deuteronomy 6:5 in English

Deuteronomy 6:5 · Berean Standard Bible

And you shall love the LORD your God with all your heart and with all your soul and with all your strength.*

Context

3Gbọ́ ìwọ Israẹli, kí o sì ṣọ́ra láti gbọ́rọ̀, kí ó bá à lè dára fún ọ, kí o bá à lè gbilẹ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ní ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti fún oyin, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba rẹ ti ṣèlérí fún ọ. 4Gbọ́ ìwọ Israẹli, Olúwa Ọlọ́run wa, Olúwa kan ni. 5Fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ. 6Àwọn àṣẹ tí mo fún un yín lónìí gbọdọ̀ máa wà lóókan àyà yín. 7Ẹ fi kọ́ àwọn ọmọ yín gidigidi. Bí ẹ bá jókòó nínú ilé, ẹ jíròrò nípa wọn, àti nígbà tí ẹ bá ń rìn ní ojú ọ̀nà, bí ẹ bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí ẹ bá dìde.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.