Native Bible

Deuteronomy 6:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ, Òun nìkan ni kí o sì máa sìn, búra ní orúkọ rẹ̀ nìkan.

Deuteronomy 6:13 in English

Deuteronomy 6:13 · Berean Standard Bible

Fear the LORD your God, serve Him only, and take your oaths in His name.*

Context

11àwọn ilé tí ó kún fún gbogbo ohun mèremère tí kì í ṣe ẹ̀yin ló rà wọ́n, àwọn kànga tí ẹ kò gbẹ́, àti àwọn ọgbà àjàrà àti èso olifi tí kì í ṣe ẹ̀yin ló gbìn wọ́n. Nígbà tí ẹ bá jẹ tí ẹ sì yó, 12ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe gbàgbé Olúwa, tí o mú un yín jáde láti Ejibiti wá, kúrò ní oko ẹrú. 13Bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ, Òun nìkan ni kí o sì máa sìn, búra ní orúkọ rẹ̀ nìkan. 14Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọlọ́run mìíràn: ọlọ́run àwọn tí ó yí i yín ká; 15torí pé Olúwa Ọlọ́run yín tí ó wà láàrín yín, Ọlọ́run owú ni, ìbínú rẹ̀ yóò sì run yín kúrò ní ilẹ̀ náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.