Native Bible

Deuteronomy 6:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe gbàgbé Olúwa, tí o mú un yín jáde láti Ejibiti wá, kúrò ní oko ẹrú.

Deuteronomy 6:12 in English

Deuteronomy 6:12 · Berean Standard Bible

be careful not to forget the LORD who brought you out of the land of Egypt, out of the house of slavery.

Context

10Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá mú yín dé ilẹ̀ náà tí ó ti búra fún àwọn baba yín, fún Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu láti fi fún un yín, ilẹ̀ tí ó kún fún àwọn ìlú ńlá ńlá tí kì í ṣe ẹ̀yin ló kọ́ ọ, 11àwọn ilé tí ó kún fún gbogbo ohun mèremère tí kì í ṣe ẹ̀yin ló rà wọ́n, àwọn kànga tí ẹ kò gbẹ́, àti àwọn ọgbà àjàrà àti èso olifi tí kì í ṣe ẹ̀yin ló gbìn wọ́n. Nígbà tí ẹ bá jẹ tí ẹ sì yó, 12ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe gbàgbé Olúwa, tí o mú un yín jáde láti Ejibiti wá, kúrò ní oko ẹrú. 13Bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ, Òun nìkan ni kí o sì máa sìn, búra ní orúkọ rẹ̀ nìkan. 14Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọlọ́run mìíràn: ọlọ́run àwọn tí ó yí i yín ká;

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.