Deuteronomi 33:8
Deuteronomy 33:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ti Lefi ó wí pé, “Jẹ́ kí Tumimu àti Urimu rẹ kí ó wà pẹ̀lú ẹni mímọ́ rẹ. Ẹni tí ó dánwò ní Massa, ìwọ bá jà ní omi Meriba.
Deuteronomy 33:8 in English
Deuteronomy 33:8 · Berean Standard Bible
Concerning Levi he said: “Give Your Thummim to Levi and Your Urim to Your godly one,* whom You tested at Massah * and contested at the waters of Meribah.*
Context
6“Jẹ́ kí Reubeni yè kí ó má ṣe kú,
tàbí kí ènìyàn rẹ mọ níwọ̀n.” 7Èyí ni ohun tí ó sọ nípa Juda:
“Olúwa gbọ́ ohùn Juda
kí o sì mú tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ wá.
Kí ọwọ́ rẹ̀ kí ó tó fún un,
kí ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀!” 8Ní ti Lefi ó wí pé,
“Jẹ́ kí Tumimu àti Urimu rẹ kí ó wà
pẹ̀lú ẹni mímọ́ rẹ.
Ẹni tí ó dánwò ní Massa,
ìwọ bá jà ní omi Meriba. 9Ó wí fún baba àti ìyá rẹ pé,
‘Èmi kò buyì fún wọn.’
Kò mọ àwọn arákùnrin rẹ̀,
tàbí mọ àwọn ọmọ rẹ̀,
ṣùgbọ́n ó dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀,
ó sì pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́. 10Ó kọ́ Jakọbu ní ìdájọ́ rẹ̀
àti Israẹli ní òfin rẹ̀.
Ó mú tùràrí wá síwájú rẹ̀
àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹbọ sísun sórí i pẹpẹ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.