Deuteronomi 32:18
Deuteronomy 32:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ kò rántí àpáta, tí ó bí ọ; o sì gbàgbé Ọlọ́run tí ó dá ọ.
Deuteronomy 32:18 in English
Deuteronomy 32:18 · Berean Standard Bible
You ignored the Rock who brought you forth; you forgot the God who gave you birth.
Context
16Wọ́n sì fi òrìṣà mú un jowú,
ohun ìríra ni wọ́n fi mú un bínú. 17Wọ́n rú ẹbọ sí iwin búburú, tí kì í ṣe Ọlọ́run,
ọlọ́run tí wọn kò mọ̀ rí,
ọlọ́run tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ farahàn láìpẹ́,
ọlọ́run tí àwọn baba yín kò bẹ̀rù. 18Ìwọ kò rántí àpáta, tí ó bí ọ;
o sì gbàgbé Ọlọ́run tí ó dá ọ. 19Olúwa sì rí èyí ó sì kọ̀ wọ́n,
nítorí tí ó ti bínú nítorí ìwà ìmúnibínú àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ. 20Ó sì wí pé, “Èmi yóò pa ojú mi mọ́ kúrò lára wọn,
èmi yóò sì wò ó bí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí;
nítorí wọ́n jẹ́ ìran alágídí,
àwọn ọmọ tí kò sí ìgbàgbọ́ nínú wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.