Native Bible

Deuteronomy 3:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gòkè lọ sí orí òkè Pisga, sì wò yíká ìwọ̀-oòrùn, ìlà-oòrùn, àríwá àti gúúsù. Fi ojú ara rẹ wo ilẹ̀ náà níwọ̀n bí ìwọ kò tí ní kọjá Jordani yìí.

Deuteronomy 3:27 in English

Deuteronomy 3:27 · Berean Standard Bible

Go to the top of Pisgah and look to the west and north and south and east. See the land with your own eyes, for you will not cross this Jordan.

Context

25Jẹ́ kí n kọjá lọ wo ilẹ̀ rere ti ìkọjá Jordani, ilẹ̀ òkè dídára nì àti Lebanoni.” 26Ṣùgbọ́n torí i tiyín, Olúwa Ọlọ́run bínú sí mi kò sì gbọ́ tèmi. Olúwa sọ wí pé, “Ó tó gẹ́ẹ́, ìwọ kò gbọdọ̀ sọ ohunkóhun lórí ọ̀rọ̀ yìí sí mi mọ́. 27Gòkè lọ sí orí òkè Pisga, sì wò yíká ìwọ̀-oòrùn, ìlà-oòrùn, àríwá àti gúúsù. Fi ojú ara rẹ wo ilẹ̀ náà níwọ̀n bí ìwọ kò tí ní kọjá Jordani yìí. 28Ṣùgbọ́n yan Joṣua, kí o sì gbà á níyànjú, mú un lọ́kàn le, torí pé òun ni yóò síwájú àwọn ènìyàn wọ̀nyí kọjá, yóò sì jẹ́ kí wọn jogún ilẹ̀ náà tí ìwọ yóò rí.” 29Báyìí ni a dúró ní àfonífojì ní ẹ̀bá Beti-Peori.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.