Native Bible

Deuteronomy 3:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

(Ogu tí í ṣe ọba Baṣani nìkan ni ó ṣẹ́kù nínú àwọn ará Refaimu. Ibùsùn rẹ̀ ni a fi irin ṣe, ó sì gùn ju ẹsẹ̀ bàtà mẹ́tàlá lọ ní gígùn àti ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà ní ìbú. Èyí sì wà ní Rabba ti àwọn Ammoni.)

Deuteronomy 3:11 in English

Deuteronomy 3:11 · Berean Standard Bible

(For only Og king of Bashan had remained of the remnant of the Rephaim. His bed of iron, nine cubits long and four cubits wide,* is still in Rabbah of the Ammonites.)

Context

9(Àwọn ará Sidoni ń pe Hermoni ní Sirioni. Àwọn Amori sì ń pè é ní Seniri). 10Gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè olórí títẹ́ náà ni a gbà àti gbogbo Gileadi, àti gbogbo Baṣani, títí dé Saleka, àti Edrei, ìlú àwọn ọba Ogu ní ilẹ̀ Baṣani. 11(Ogu tí í ṣe ọba Baṣani nìkan ni ó ṣẹ́kù nínú àwọn ará Refaimu. Ibùsùn rẹ̀ ni a fi irin ṣe, ó sì gùn ju ẹsẹ̀ bàtà mẹ́tàlá lọ ní gígùn àti ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà ní ìbú. Èyí sì wà ní Rabba ti àwọn Ammoni.) 12Nínú àwọn ilẹ̀ tí a gbà ní ìgbà náà, mo fún àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi, ní ilẹ̀ tí ó wà ní àríwá Aroeri níbi odò Arnoni, pọ̀ mọ́ ìdajì ilẹ̀ òkè Gileadi pẹ̀lú gbogbo ìlú wọn. 13Gbogbo ìyókù Gileadi àti gbogbo Baṣani, ní ilẹ̀ ọba Ogu ni mo fún ìdajì ẹ̀yà Manase. (Gbogbo agbègbè Argobu ni Baṣani tí a mọ̀ sí ilẹ̀ àwọn ará Refaimu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.