Native Bible

Deuteronomy 28:44 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Yóò yà ọ́, ṣùgbọ́n o kì yóò yà á, òun ni yóò jẹ́ orí, ìwọ yóò jẹ́ ìrù.

Deuteronomy 28:44 in English

Deuteronomy 28:44 · Berean Standard Bible

He will lend to you, but you will not lend to him. He will be the head, and you will be the tail.

Context

42Ọ̀wọ́ eṣú yóò gba gbogbo àwọn igi rẹ àti àwọn èso ilẹ̀ rẹ. 43Àjèjì tí ń gbé láàrín rẹ yóò gbé sókè gíga jù ọ́ lọ, ṣùgbọ́n ìwọ yóò máa di ìrẹ̀sílẹ̀. 44Yóò yà ọ́, ṣùgbọ́n o kì yóò yà á, òun ni yóò jẹ́ orí, ìwọ yóò jẹ́ ìrù. 45Gbogbo ègún yìí yóò wá sórí rẹ, wọn yóò lé ọ wọn yóò sì bá ọ títí tí ìwọ yóò fi parun, nítorí ìwọ kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ, ìwọ kò sì kíyèsi àṣẹ àti òfin tí ó fi fún ọ. 46Wọn yóò jẹ́ àmì àti ìyanu fún ọ àti fún irú-ọmọ rẹ títí láé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.