Deuteronomi 28:3
Deuteronomy 28:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìbùkún ni fún ọ ni ìlú, ìbùkún ni fún ọ ní oko.
Deuteronomy 28:3 in English
Deuteronomy 28:3 · Berean Standard Bible
You will be blessed in the city and blessed in the country.
Context
1Bí ìwọ bá gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ ní kíkún kí o sì kíyèsára láti tẹ̀lé gbogbo ohun tí ó pàṣẹ tí mo fi fún ọ lónìí, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbé ọ lékè ju gbogbo orílẹ̀-èdè ayé lọ. 2Gbogbo ìbùkún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ bí o bá gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ. 3Ìbùkún ni fún ọ ni ìlú, ìbùkún ni fún ọ ní oko. 4Ìbùkún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èso ilẹ̀ rẹ, àti irú ohun ọ̀sìn rẹ àti ìbísí i màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ. 5Ìbùkún ni fún agbọ̀n rẹ àti fún ọpọ́n ipò ìyẹ̀fun rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.