Deuteronomi 28:2
Deuteronomy 28:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo ìbùkún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ bí o bá gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.
Deuteronomy 28:2 in English
Deuteronomy 28:2 · Berean Standard Bible
And all these blessings will come upon you and overtake you, if you will obey the voice of the LORD your God:
Context
1Bí ìwọ bá gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ ní kíkún kí o sì kíyèsára láti tẹ̀lé gbogbo ohun tí ó pàṣẹ tí mo fi fún ọ lónìí, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbé ọ lékè ju gbogbo orílẹ̀-èdè ayé lọ. 2Gbogbo ìbùkún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ bí o bá gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ. 3Ìbùkún ni fún ọ ni ìlú, ìbùkún ni fún ọ ní oko. 4Ìbùkún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èso ilẹ̀ rẹ, àti irú ohun ọ̀sìn rẹ àti ìbísí i màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.